Offline
READ RHAPSODY Today's Devotional in Yoruba
By King Joe Kima
Published on 12/05/2025 08:56 • Updated 04/07/2025 07:33
Rhapsody of Realities

ÀṢẸ TÒÓTỌ WÀ PẸ̀ LÚ ỌLỌ́RUN À

Bí wọ́ n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ , èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́ yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jẹ ọba (Dáníẹ́ lì 4:26).

Bíbélì sọ, nínú Dáníẹ́ lì 4, sọ nípa bí Nebukadinésárì ṣe lá àlá kan tó dà á láàmú gan-an. Nínú àlá yìí, ó rí igi àgbàyanu kan tó ga tó sì lágbára, tó ń pèsè ibi ààbò àti oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀ dá alààyè. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́ n pàṣẹ fún áńgẹ́ lì kan pé kí wọ́ n gé igi náà lulẹ̀ , kí wọ́ n sì fi kùkùté kan ṣoṣo tí a fi irin àti idẹ dè síle ̣ ̀ . Àlá yìí mú kí ọkàn ọba dàrú, ó sì kàn sí Dáníẹ́ lì, wòlíì Ọlọ́ run, láti túmọ̀ rẹ̀ .

Dáníẹ́ lì ṣí i payá pé ọba fúnra rẹ̀ ni igi náà, òun yóò rẹsílẹ̀ nítorí ìgbéraga re ̣ ̀ títí òun yóò fi gbà pé "ọ̀ run je ̣ ́ ọba" (Dáníẹ́ lì 4:26). Ọdún kan lẹ́ yìn náà, tí Nebukadinésárì kò tíì ronú pìwà dà, Nebukadinésárì; ó sì di wèrè fún ọdún méje, ó gbé bí ẹranko, ó ń jẹ koríko, ó sì ń rìn kiri nínú oko.

Gẹ́ gẹ́ bí Dáníẹ́ lì 4:17 ti sọ,pr àṣẹ yìí wá láti ọ̀ dọ̀ "àwọn olùṣọ́ " pé: ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀ dọ̀ ẹni mímọ́ , kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀ lẹ̀ lórí i wọn." À̀wọn " olùṣọ́ " níhìn-ín ń tọ́ ka sí àwọn ẹ̀ dá áńgẹ́ lì tí a yàn láti bójú tó ọ̀ ràn lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀ lú ọlá àṣẹ láti fipá mú ìfẹ́ Ọlọ́ run.

Nebukadinésárì rò pé òun ń ṣàkóso ayé, títí tí a fi fipá mú mú un láti jẹ́ wọ́ ìṣàkóso ọ̀ run. Ó rí bá kanna lónìí. Àwọn tí wọ́ n fi irọ́ pípa sọ pé wọ́ n ní ọlá àṣẹ pípé lórí àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́ n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ẹ̀ tàn pé ipa tí wọ́ n ní, fún wọn ni agbára ìdarí lórí àwọn orílẹ̀ -èdè, wọn ò mọ̀ pé ọlá àṣẹ tòótọ́ wà pẹ̀ lú Ọlọ́ run àti Ìjọba Rẹ̀ ti ọ̀ run. Gbogbo agbára je ̣ ́ ti Olúwa, Ó sì ńse àwọn idajọ Rẹ lórí ile ̣ ̀ ayé nípasẹ̀ Ì̀ jọ: “Jésù si wá sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbára ni ati fi fún mi ní ọ̀ run àti ní ayé.” (Máttíù 28:18). 

A fi agbára mú ìfẹ́ Ọlọ́ run sẹ nínú ayé wa: “èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́ wọ́ ọ̀ tún nínú àwọn ọ̀ run. Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́ n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀ lú. Ọlọ́ run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ , ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, èyí tí i ṣe ara rẹ̀ , ẹ̀ kúnrẹ́ rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀ nà.” (Éfésù 1:20-23). Halleluyah! 

PRAYER

Baba mi Olùfẹ́ , mo dúpẹ́ lọ́ wọ́ rẹ fún ìdánilójú pé àwọn ọ̀ run je ̣ ́ ọba àti pé gbogbo agbára jẹ́ tìrẹ. inu mi dùn si mímọ̀ pe gbogbo àwọn ìjọba ayé yìí ni yóò tẹriba fún Olúwa Jésù Kristi. Mo kéde pé ìfẹ́ àti ète rẹ borí àwọn orílẹ̀ -èdè, ọlá àṣẹ rẹ sì jọba tó ga jù lọ, ní Orúkọ Jesu’. Àmin.

FÚN ÌTẸ̀SÍWÁJÚ Ẹ̀KỌ́:

Orin Dafidi 103:19; Danieli 7:13-14; Matteu 28:18-19

ÈÈTÒ FUN KÎKA BIBELI JÁ LỌ́DÚN KAN:

IŒe awön Aposteli 17:1-15 & Jobu 3-5

ÈÈTÒ FUN KÎKA BIBELI JÁ LỌ́DÚN MÉJÌ

Luku 6:31-38 & Deuteronomi 32

Comments
Comment sent successfully!